Ẹ kaabọ si:
Ileesẹ Ajọ Orilẹ Yorùbά Lẹyin-Odi
Ti Ilẹ Gẹẹsi ati Orilẹ-Ede Amẹrika.
Ẹka Orilẹ Yoruba (lẹyin odi) to wa fun awọn ohun to je mọ Idẹrun ati Igbaye-gbadun (YCWSS- Ti Awujọ BAME)
Fun gbogbo awọn eni to jẹ Yorùbά ni gbogbo ibikitibi ti wọn ba wa ni agbaye eleyii ti o si bẹrẹ lati Ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ Amẹrika.
ALAYE IPILẸ ATI IBẸRẸ PẸPẸ
Ṣiṣi Ileeṣẹ to wa fun orilẹ Yorùbά ti yoo maa sisẹ lati ẹyin odi ni ilẹ Gẹẹsi ati ni ilẹ Amẹrika jẹ igbeesẹ akin lati safihan ipinnu awọn ọmọ Yorùbά nilẹ (ilẹ Yorùbά) to wa ni apa Iwọ-oorun ilẹ-Adulawọ (Afrika) ati awọn to wa kaakiri gbogbo agbeye nipa ati-safihan re pe a kapaa sise agbekalẹ ati akoso awujọ agbarijọ gbogbo Yorùbά pẹlu ẹmi isọkan ati ilepa igbaye-gbadun ọmọ-lakeji ti a ti da mọ wa yoo jẹ ọpa kutẹlẹ rẹ, oun ninifẹẹ ọmọlekiji ti wọn ti fi kọ wa lati ile wa ati jijẹ ki ọrọ ọmọlakeji mu wa lọkan ni ibikibi ti a ba ti pade lagbaaye pẹlu igbaradi oun sisetan alailegbe wa fun ipinnu ọka-ara-ẹni.
Ileeṣẹ ajọ to n mojuto idẹrun ati igbaye-gbadun orilẹ Yorùbά lẹyin odi (YCWSS) jẹ ẹka akọkọ fun ileeṣẹ Ajọ orilẹ Yorùbά lẹyin odi. O jẹ ẹka ti awọn osisẹ (ẹni-bi- ẹni) to fira wọn jin fun iru isẹ yii wa, o si tun jẹ akọkọ iru ileesẹ to n ṣiṣẹ lati ẹyin odi eleyii ti eekan awọn ọmọ Yorùbά se agbatẹru rẹ fun awọn ọmọ-bibi Yorùbά ti wọn n gbe lẹyin odi ilẹ Yorùbά. Idi niyi to fi jẹ pe idasilẹ rẹ n salaye, o si tun jẹ ibẹrẹ akọkọ iru ajọ Ileeṣẹ-Orilẹ Yorùbά lẹyin odi bi iru rẹ ni gbogbo agbaye. Awọn iru ileesẹ ajọ to n sise lati ẹyin odi bii iru rẹ ( ti wọn nii se pẹlu orilẹ kan-si-omiran) naa yoo fi eyi se awokọse lati ṣeru rẹ lọgan ti wọn ba ti gbasẹ lati se bẹẹ. Awa Yorùbά ti pinnu, a si ti setan lati se agbekalẹ awujọ to gbórίn ti si rẹsẹ walẹ ni gbogbo orilẹ yoowu ti a ba ti ba ara wa ni gbogbo agbanla aye eleyii to jẹ pe ẹkọ-ile to jinlẹ, ti ko se e fọwọ rọ sẹyin oun asa abinibi wa ti a jogun lati ọdọ awọn obi wa ati awọn to tọ wa gbogbo ni ọpa kutẹlẹ rẹ, eleyii ti o seese ki ọpọlọpọ akoko ti a ti lò lẹyin odi ti se akoba nla-nlaa fun paapaa bo se jẹ pe a ti jinna si Apa-Iwọ oorun Afrika ati ilẹ Yorùbά gan an pupọ ṣugbọn ti a si pinnu lati ma jẹ ko parun.
Ko si ani-ani pe lara asa ati isẹse ayebaye ilẹ Yorùbά ni a ti ri awọn amuye bii Iranra-ẹni-lọwọ, ikunni-lọwọ ibagbepọ, ikonimọra, fifi-aaye-gbani, ifọwọ-sowọpọ. sise-apọnle, ibọwọ-fagba ati ififun-ni tabi itọrẹ (ẹbun) fun ati onile ati alejo ati ẹru atọmọlabi (se bi a ṣe bi ẹru la bi ọmọ) iyẹn lọpọ igba ti a ba ni anito ati aniṣẹku. Awọn asa ati isẹse wọn ni awọn orilẹ-miiran kaakiri agbaye ni wọn maa n sajeji si wa lọpọ igba, ti wọn kii ba wa lara mu rara, ti wọn si maa n se akoba fun igbe aye idẹrun wa, paapaa nibi to ba ti jẹ pe alamulegbe kọọkan ba ti n se konko jabele-kii da si alamulegbe keji rẹ. debi pe a tiẹ lee ma mọ ẹni to n gbe nile keji to fẹgbẹ ti wa taa si jọ n gbe lẹgbẹ ara wa fun ọpọlọpọ ọdun.
AJỌ YCWSS – NI IGBESẸ TO KAN (LATI GBE)
Ṣiṣe agbekalẹ ileeṣẹ Ajọ-orilẹ Yorùbά ti yoo maa boju to idẹrrun ati igbaye-gbadun gbogbo ọmọ Yorùbά lati ẹyin odi eleyii ti a da pe ni YCWSS ni igbesẹ akin to sun kan fun gbogbo ọmọ Yorùbά to n gbe ni ẹyin odi ilẹ Yorùbά ti apa Iwọ-Oorun ilẹ-Afrika lati ṣalaye ati lati se agbekalẹ to mọyan-lori, lati se ipolongo to la gbogbo agbaye ja, ati lati kede pe a ti balẹ bagẹ fun gbogbo agbaye lati ri ki wọn si mọ gẹgẹ bii ẹya to laakun-laaka eleyii ti a si to ẹgbẹẹgbẹrun lona- ẹgbẹrun niye kaakiri gbogbo agbaye lati pese ohun gbogbo ti a nilo lati orilẹ-kan-si omiran gẹgẹ bi a se gbọ iroyin rẹ ni ilẹ Gẹẹsi ati orilẹ-ede Amerika. Ẹya Yorùbά to ni iye eniyan to pọ julọ niye ninu gbogbo ẹya to wa lorilẹ Naijiria eleyii ti oun naa jẹ orile to ni iye eniyan to pọ julọ ni gbogbo ilẹ-Adulawọ (Afirika) nipa idi eyi ni ẹya kan ṣoṣo to jẹ dudu to gbọrẹgẹ-jigẹ ni gbogbo agbaye. Nipa idi eyi a ti kogo ja, a peregede, a fi gbọọrọ jẹka o si ti to akoko tipẹ-tipẹ fun wa lati ni orilẹ olominira ti wa eleyii ti a o tun nii maa ṣe ajọpin rẹ pẹlu ẹya /orilẹ Kankan mọ.
Nipasẹ akitiyan ati igbokegbodo ajọ ti a n da pe ni YCWSS yii, a ti bẹrẹ sii gbe igbesẹ akin lati pe gbogbo awọn eeyan wa jọ papọ kaakiri gbogbo agbaye, lati lee samulo gbogbo awọn ẹkọ olowo iyebiye ti a ti kọ nile sẹyin, abala asa wa to daa julọ nipa ifira- ẹni-jin ati fifunni ati bi a se pọ to ni onka ni ọpọlọpọ awọn orilẹ kaakiri agbaye lati bẹrẹ sii sisẹ to sisẹ agbekalẹ awọn awujọ ti a lee pe ni tiwa gan-an, fun awọn eniyan wa ati ni Pataki julọ fun ominira orilẹ Yorùbά ni Iwọ-Oorun Afirika. Eyi to ga ju ninu awọn akitiyan wa ni lati ri i pe a fi awọn Ọba Yorùbά jẹ ni ilẹ Gẹẹsi ati ni Orilẹ Ede Amerika. Ọmọ Yorùbά to ẹgbẹẹ-gbẹrun lọna ẹgbẹrun niye ni awọn orilẹ mejeeji ti a darukọ yii. Eyi nikan si to ni ẹri ati awijare wa fun awọn igbesẹ yii, eleyii ti erongba rẹ jẹ ọna lati se igbelarugẹ ati lati ṣe lọjo asa ati iṣẹṣe oun ede Yorùbά wa ni gbogbo agbaye Aijẹbẹẹ, Ọlọun ma jẹ ki Yorùbά o tẹri sinu agbami okun awọn asa ajeji gbogbo. A o ri i daju pe a gbe ihinrere ọrọ nipa ẹya Yorùbά de ọdọ awọn eeyan wa ni ibikibi ti wọn ba wa lagbaaye, eleyii yoo si mu ki okun to so gbogbo ọmọ Yorùbά pọ o tun le dain dain sii.
Oju opo ayelukara ti itakun agbaye WEBSITE ajọ yii yoo maa se afikun ati afihan awọn ise ati ileeṣẹ titun titun miiran, awọn ọrọ miiran to ba nii ṣe pẹlu wọn ati iṣẹ ti wọn kapa lati se gbogbo. Awọn iṣẹ ti wọn saaju wọnyi yoo maa jẹ pipese ni Ilẹ Gẹẹsi ati ni Orilẹ- Amẹrika. Bi a ba si ti n ni awọn orilẹ-titun miiran pẹlu, logan ni a o maa se afikun wọn ti a o si maa kede wọn pẹlu lori itakun ayelukara WEBSITE yii kan naa.
Ọfẹ ni gbogbo awọn ohun ti a o maa se fun yin lori itakun yii. Iyẹn fun gbogbo ẹni to ba jẹ ọmọ Yorùbά, yoo si maa de ọdọ yin lati ipasẹ awọn oṣiṣẹ akọṣẹ-mọṣẹ afira-ẹni jin lati ẹyin odi wa. Ẹni kọọkan ti wọn ba da lohun nipasẹ eto yii ni wọn o mu wole si inu opo ayelukara wọn, gbogbo awọn ohun to ba si yẹ lati mọ nipa ẹni to ba jẹ anfaani naa ni lilo re ko nii kọja biba-ara ẹni sọrọ pẹlu rẹ nikan lori ohun to jẹ mọ eto yii. Nipa idi eyi, awọn eniyan wa ko gbọdọ padanu nọmba asiri fun ẹrọ ibaniọrọ wọn nitori pe awọn to ba forukọ silẹ nikan ninu awọn to ba jẹ anfaani nikan ni a o jọ maa sọrọ papọ, a si tun lee lanfaani lati maa ba awọn asoju wọn tabi awọn obi/alagbatọ wọn sọrọ pọ iyẹn bo ba jẹ ọmọde ni ẹni too jẹ anfaani naa. Gbogbo ọrọ nipa ẹni kọọkan ni yoo jẹ ṣiṣe lọjọ lọdọ ajọ ti a da pe ni YCWSS yii eleyii to se pe bi eni to ni i ba ni ka fi sita lo ku ti a o se bẹ, ti yoo si wa ni ibamu pẹlu ofin ajọ GDPR ti ọdun 2018 ati aato oun ilana/alakalẹ agbekalẹ ajọ YNCS ati ti YCWSS gbogbo.
Inu wa yoo dun bi a ba ri awọn afira- ẹni-jin oṣiṣẹ lẹyin odi titun ti wọn ṣe tan lati dara pọ mọ wa. Tayọ-tayọ ni a o si fi gba wọn mọra pẹlu. Gbogbo awọn oninu-didun ọlọrẹ pata ni a n reti, a o si ni i sai maa lu yin lọgọ ẹnu nipa fifi ẹmi imoore han. Ẹ lee pe eyikeyii ninu awọn ẹrọ ibanisọrọ tẹlifoonu to wa nisalẹ wọnyi. Gbogbo awọn ti wọn ba ṣe tan lati fi ara jin fun iṣẹ yii ni wọn o kopa ti wọn si gbọdọ yege ninu eto idanilẹkọọ lati ibẹrẹ de opin ki wọn o too lee maa ba awujọ ni ajọsepọ lori isẹ yii.
Gbogbo ofin ilana ati agbekalẹ ajọ YNCS ati YCWSS ni yoo si maa jẹ mimulo ati titẹle paapaa eleyii to ni ise pẹlu igbelewọn atigba-degba pẹlu ayẹwo oun ijanu lati ọdọ ajọ ti a da pe ni DBS. A ko ni faaye gba iwa ibajẹ tabi asilo ipo lati ọdọ oṣiṣẹ afira-ẹni-jin yoowu bo ti wu ko mọ, a si lero pe gbogbo awọn to ba jẹ anfaani eto yii naa yoo maa se apọnle ati ayẹsi awọn oṣiṣẹ afira-ẹnijin wa ati gbogbo awọn to ba pe wọn. A ni aṣẹ lati fopin si anfaani ẹni to ti n jẹ anfaani tẹlẹ, tabi ki a tiẹ fagi le aaye ẹni to ti n jẹ anfaani tẹlẹ ka si gbe e fun ẹlomiran to wu wa ni igbakugba ati lai ni ajọsọ-ọrọ tẹlẹ lori rẹ.
Akọmọna wa ni yoo maa fi gbogbo igba tẹle alakalẹ ilana ati ti akọṣẹ-mọṣẹ. Awọn ohun ti o ba si wa ni ikawọ wa ni ṣiṣe la o maa pese, niwọn igba to ba ti ba ofin mu ti a si ni ohun gbogbo ti a nilo lati pese rẹ ni ikawọ wa.
A n reti imọran to dara, to si se anfaani lati ọdọ gbogbo ọmọ Yorùbά gẹgẹ bi o se jẹ pe eto yii wa fun gbogbo ọmọ bibi ilẹ Yorùbά kaakiri agbaye ni. Ileeṣẹ to n ri si orilẹ-Yorùbά lẹyin odi ti a n da pe ni YNCS se tan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu Ileeṣẹ tabi ajọ yoowu to ba ni afojusun tabi agbekalẹ bii tiwa yii.
AWỌN IṢẸ IFIRA-ẸNI JIN
Ileeṣẹ ajọ to n ri si agbekalẹ orilẹ Yorùbά lẹyin odi eleyii ti a da pe ni YNCS ni awọn eto idẹrun ati amayetura wọnyii fun ajọ ti a n pe ni BAME Yorùbά Community ni Ilẹ-Gẹẹsi ati Orilẹ Ede Amẹrika.
ETO IBARA-ẸNI SỌRỌ LORI ẸRỌ TẸLIFOONU TI KII FIGBA KANKAN DURO
Nipasẹ eto yii ni a fi n gba eeyan wọle ti a si n se iforukọ silẹ akọkọ fun gbogbo awọn eto wa yooku ayafi iba diẹ. Oun naa tun ni oju opo fun gbogbo ẹni to ba fẹẹ ṣewadii ohun kan tabi omiran nipa awọn ohun to n lọ lọwọ-lọwọ ni orilẹ-ede tabi ilu ti o ba wa lẹyin odi, eleyii to n gbe. Nipasẹ eyi ni ẹ ti lee se ohun to ba jẹ pajawiri/yajo-yajo, ohun ti a ba fẹẹ mọ ati imọran alakalẹ eto/ ilana aa tẹle, awọn iṣẹlẹ to n sẹlẹ, bi a se le e di ẹni tara re yoo mọle, awọn ohun ti ofin sọ, bi wọn se n se nibi to o wa, imọ-si-lara wọn si isẹlẹ ati si awọn eeyan ati bẹẹ bẹẹ lọ Eyi tun ni se pẹlu imọran oun ilana lori bi awujọ ọmọ Yorùbά yoo se fifi lọlẹ ati bi wọn o se maa jẹ awọn anfaani ti a gbe kalẹ fun awọn awujọ onibilẹ-jibilẹ lawọn orilẹ-ede ati agbegbe ti a ba n gbe ati awọn nnkan miiran- Bi o tilẹ jẹ pe lọwọ-lọwọ bayii, Ilẹ-Gẹẹsi ati Orilẹ-Ede Amẹrika lawọn anfaani yii si wa bayii. To ba see se, awọn eto miiran to ba kan tun lee jẹ sise leyin ipe fun igba akoko lori erọ ibanisọrọ telifoonu. A o maa se afikun awọn eto ati ise ti a n pese fawọn orilẹ miiran bi a ba se n ni awọn oṣiṣẹ afira-ẹni-jin lawọn lorilẹ naa.
ỌRỌ TO NI SE PẸLU IRIN-AJO SI ORILẸ MIIRAN, IGBELUU ATI DIDI ỌMỌ ONILUU/NINI IWE IGBELUU
A ti ni awọn amofin to dantọ ati awọn akọṣẹ-mọṣẹ laarin awọn ọmọ Yorùbά wa ti wọn ti gba, ti wọn si ṣe tan lati se iranwọ lọpọ-lọpọ eleyii to si see se ko ma ni owo sisan ninu pelu (ti o jẹ Ọfẹ)
ETO NIPA AWỌN ILE ITAJA ATI AWỌN ỌJA TO JẸ TI YORUBA
Lọwọ-lọwọ bayii, a ti n se atojọ orukọ awọn ile- itaja to jẹ ti awọn ọmọ Yorùbά ni ilẹ Gẹẹsi ati ni Amẹrika. A o fun un yin ni itoni ati imọran lori awọn orukọ ti a ti ko jọ naa.
ỌRỌ NIPA RIRIN-IRIN-AJO (LILỌ SI) ATI GBIGBE NI OKE OKUN
Ẹ jọwọ, e pe awọn nọmba ẹrọ ibara-ẹni sọrọ awọn oṣiṣẹ wa ti ẹ ba n rin irin ajo lo si Ilu Ọba- Ilẹ Gẹẹsi (U.K) ati Orilẹ-Ede Amẹrika (USA) paapaa julọ ti iru ẹni bẹẹ ba jẹ, arinrin ajo fun igba akọkọ to si nilo iranwọ akọkọ ti “ko-delẹ-yii-ri” maa n nilo lati mọ bi yoo o ti se niluu ti o de tabi lati tete ri ibukokoo irọrun nibẹ.
ETO FUN ITỌJU AWỌN ARUGBO ATI AWỌN IṢẸ AWUJỌ MIIRAN
Ni ibami pẹlu ofin ati ilana to nii ṣe pẹlu iru iṣẹ yii ni inu ilu orilẹ kọọkan, a o maa se awọn eto abẹwo ifarakinra, imutẹsiwaju ati awọn eto miiran, gẹẹ bi o se maa n se nile lọhun-un (Nilẹ- Yorùbά) fun awọn ọmọ orilẹ- Yorùbά to jẹ arugbo, ti wọn si niwee igbeluu. Ṣugbọn ọwọ awọn to ba nifẹẹ si eto yii, ti wọn si fi orukọ silẹ pẹlu wa fun eto naa ni yoo jẹ anfani rẹ.
ETO IDANILẸKỌỌ ATI IMUDAGBASOKE.
Awọn eto to jẹ mọ ede, Aṣa ati iṣẹse, jijẹ-ọmọ-onilu, akoso oun iṣejọba Yorùbά, ati kikopa ninu eto iṣelu ati awọn eto miiran ti yoo wa fun awọn ọdọ, awọn iyalọmọ ti ko si nile ọkọ, awọn to ti dagbalagba ati fun gbogbo awọn eniyan awujọ ti wọn nifẹẹ si ọrọ orilẹ Yorùbά ni a o maa se igbelarugẹ ati idagbasoke fun. A o ri i pe a ṣe iforukọ-silẹ pẹlu awọn ajọ to ni ontẹ ijọba labẹle gẹgẹ bi ara eto ati alakalẹ lati lee ri eto ati iṣẹ yii se bo se yẹ.
ETO FUN IBATAN ẸNI TO KANNI GBONGBON / ẸNI TO SUN MONI JULỌ
A maa n se iru eto yii gẹgẹ bi iranwọ fun awọn eniyan wa, nigba ti wọn ba ti tọ si i, ti wọn si ni gbogbo amuyẹ to rọ mọ ọn.
ETO NIPA OHUN TO N LỌ NILẸ YORUBA
A o nii jẹ keti awọn eeyan wa to ba beere nipa ile ko di lori awọn isẹlẹ to n sẹlẹ nile lọhun un, ni ẹkun rẹrẹ ati ni yajo-yajo. Bo ba se n tẹ wa lọwọ paapaa julọ lawọn asiko ti nnkan ko fararọ. A ti ni ibasepọ ati awọn ọna lati ri awọn ileesẹ iroyin ba sọrọ pẹlu awọn eeyan wa to jẹ Yorùbά kaakiri gbogbo agbaye. Ko si si ohun to n lọ, ta o lee gbọ lati ọdọ wọn.
ETO TO NII SE PẸLU AGBEKALE/AKỌSILẸ ISẸ IWADII IMỌ IJINLẸ AWỌN AKẸKỌỌ
Gbogbo ọna ni a n gba se iranwọ lori awọn akanse isẹ imọ ijinlẹ ati iwadii alakada bii ṣise agbekalẹ ati ṣiṣe- awari atojọ-ibeere-eleto ( fun isẹ iwadii) ṣiṣe iranwọ lori hiha ati pinpin rẹ oun iranwọ lori kiko pamọ si aka. Iru isẹ iwadii imọ imọ ijinlẹ iwadii bẹẹ lee jẹ lori eyikeyii ẹka to nii ṣe pẹlu Aṣa ati Iṣẹse Yorùbά, Ilẹ Yorùbά, Orilẹ Yorùbά tabi awọn Ẹya Yorùbά kaakiri gbogbo agbaye.
ETO TO NII SE PẸLU YIYANJU AAWỌ PẸLU IRIRI AWỌN AGBAAGBA Ti A DA PE NI ( AGBA KO NII TAN NILE YORUBA)
Awọn ọrọ ati iṣẹlẹ kan wa ti o seese ko waye laarin awọn ọmọ Yorùbά ti -wọn jọ n se asepọ tabi ọrọ ẹbi to ṣe pe ẹnu awọn agba lo yẹ ki obi iru ọrọ bẹẹ o ti gbo, to si yẹ ko jẹ pe awọn agba lo yẹ ko yanju iru aawọ bẹẹ - Iyẹn awọn Agba ilẹ Yorùbά. A o se gbakalẹ igbimọ agba Yorùbά awọn ti wọn ti dagba ni ọgbọn imọ oye ti wọn si ni ọpọ iriri nipa ile aye ati ọrọ to nii se pẹlu ẹya Yorùbά, ti wọn o si lee jokoo, lati fun awọn tọrọ kan ni ọgbọn oun imọran agba, iyẹn ti awọn tọrọ kan ba gba pe kiru ijokoo bẹẹ o waye, gẹgẹ bi awọn baba-wa se maa n pa a lowe pe”AGBA KII WA LỌJA, KORI ỌMỌ TITUN O WỌ” toto o ṣe bi owe. Eleyii yoo gbinaya nipasẹ, ajọ YCWSS nigbẹyin-gbẹyin, a o ṣe agbekalẹ kootu ibilẹ tiwa eleyii ti yoo maa jfokoo ti yoo maa gbejọ, ti yoo si maa ṣe atungbeyẹwo awọn ejọ/ọrọ to ba nii se pẹlu ọmọ Yorùbά kan si omiran.
AWỌN, AWUJỌ YORUBA TI AJAKALẸ ARUN COVID 19’ FỌWỌ BA
A o ni eto to kun rere ninu awọn eto to wa nilẹ fun awọn ọmọ Yorùbά ni awujọ Yorùbά yoowu ko jẹ ti kokoro arun COVID 19’ ti se akoba fun, titi to fi de ori awọn Yorùbά, ebi ati awọn oṣiṣẹ tọrọ naa gbe ru ti wọn nipin-in nibẹ.
ETO IRANWỌ NIPA ṢIṢE AANU FUN AWỌN TO NILO IRANWỌ
Eleyii ni yoo maa jẹ mimu de awọn ibi to ye lati ọdọ awọn oṣiṣẹ wa nipasẹ awọn ẹka akosọ ati awọn alasẹ ni ilu kọọkan ni gbogbo orilẹ. A o nii fi yin silẹ lai da si. Gbogbo awọn ohun to ba si jẹ ẹtọ ati anfaani yin ni yoo jẹ gbigba pada fun yin.
O N BỌ LỌNA…
Awọn eto alagbara miiran ti iṣe ti de ipo to lapẹrẹ lori wọn lati ileesẹ wa yii lẹyin odi ni, fifi ‘Oba Yorùbά’ jẹ ni Ilẹ Gẹẹsi ati ni Amẹrika ( eleyii lo se Pataki to si jẹ ọna ati aato lati mu ki gbogbo ọmọ Yorùbά to wa kaakiri gbogbo agbaye o wa ni isọkan). Eto ti yoo maa ri si awujọ awọn olokoowo to jẹ ọmọ Yorùbά, ṣise agbatẹru eto inawo ati onigbọwọ fun awọn akanse iṣẹ iwadii imọ ijinlẹ alakada, ṣise agbekalẹ awọn ilu Yorùbά ninu ilu LONDON ati NEW YORK kikopa ninu idokowo lori ile, awujọ awọn ọmọ Yorùbά eto idẹrun ati igbaye gbadun awọn ọmọ Yorùbά ni ile. Ẹ lee dara pọ mọ wa lori awọn eto ori afẹfẹ wa gbogbo ti a n ṣe afihan wọn bi a se n ṣe wọn lọwọ ni awọn ileese-iroyin ayelujara ati pẹlu awọn akọṣẹ -mọṣẹ wa nipa eto iroyin.
Join our programmes
Please join us on our live programmes with the following nationalist social media houses and professionals
ẸRI (MAA JẸ MI NISO)
Awọn ti wọn ti jẹ anfaani awọn eto idẹrun ati igbaye gbadun Ileeṣẹ-Ajọ Orilẹ Yorùbά lẹyin odi ti a pe ni YCWSS yii naa ni wọn, o maa funra wọn ṣe ijẹrii si awọn anfaani ti wọn ti jẹ lori awọn eto wa ti a n se lori awọn ikanni ayelujara ti ibanidọrẹẹ ni igba ati asiko ti wọn ba fẹ, ati asiko to rọ wọn lọrun pẹlu bi awọn eto wa gbogbo ba ṣe n tẹ siwaju.Wọn ke gbajare ọrọ yii de ọdọ ajọ YCWSS, a si gba ọmọ obinrin Yorùbά yii pada fun un. Koda a ko sai tun gba iya naa nimọran lati da ọmọbinrin rẹ yii pada sile lati lọ pari ẹkọ iwe rẹ oni-ipele girama / sẹkọndiri agba (SSS) ni ile. Ko si tun le e ni ẹkọ ile ati iwa ọmọluabi to ye. Lonii, ọmọbinrin ti a n sọ yii ti pari ẹkọ nipa imọ ofin rẹ, eleyii to ko nilẹ Gẹẹsi. Nijọ ayẹyẹ ikẹkọọ gboye rẹ, o sun ẹkun pẹlu omije-ayọ, o si dupẹ pupọ lọwọ awọn oṣiṣẹ afira-ẹni-jin ajọ YCWSS fun lilo ti Ọlọun lo wọn lati ma jẹ ko ṣegbe laye.
Ọpọ awọn aseyọri bi iru awọn ti a ti mẹnu ba yii lo tun kunlẹ rẹpẹtẹ to ṣe pe, wọn ki ba tii ri awọn itan aseyọri naa sọ bi kii ba a se kike ti wọn ke gbajare wa ba awọn oṣiṣẹ ajọ YCWSS. Gbogbo ọpẹ jẹ ti Oluwa Ọlọrun Eledumare, a si tun lu gbogbo awọn eeyan ti Ọlọrun lo lati ri awọn aseyọri alailẹgbẹ wọnyi ṣe lọgọ ẹnu pe Ẹ ṣeun.
Fi Inurere Ṣọrẹ Si Awọn Iṣẹ Ikẹkọ Ilu Yorùbá
Ẹbun rere rẹ yoo lọ lati ṣe atilẹyin ifihan ti ipinnu Yorùbá ti orilẹ-ede wa lati ṣe afihan agbegbe ti o ni asopọ pẹkipẹki wa si agbaye nipasẹ iṣẹ pataki ti Yorùbá Consular Welfare Services Services ‘(YCWSS) ti a n ṣe lati pese iranlọwọ, itọju ati atilẹyin bi awa fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ si gbigba ipo ọba Yorùbá tiwa.
Yoruba Consular Services Special Projects
Which Consulate are you donating to?
YCWSS Email
Call
UNITED KINGDOM
+44203-551-8625
+44779-912-7851
UNITED STATES
+1 (669) 649-3373
Official Meeting Place
Yoruba Nation Consular Services UK
64 Nile Street
London
N1 7SR
O le gba iranlọwọ Nibikibi ti o ba wa
Awọn Iṣẹ Ikẹkọ Ilu Yorùbá nfun lọwọlọwọ ni ọpọlọpọ awọn iṣẹ atilẹyin si awọn agbegbe BAME Yorùbá ni gbogbo agbaye